PropertyValue
?:author
?:datePublished
  • 2022-07-22 (xsd:date)
?:headline
  • Kò sí ẹ̀rí wípé olósèlú ati olùdupò ààrẹ ti orílẹ̀dè Nàìjíríà Bola Tinubu sopé òhun kò ní wá sí ìtàkùrọ̀sọ àwọn olùdupò ààrẹ nítorí àìlera rẹ̀ (vi)
?:inLanguage
?:itemReviewed
?:mentions
?:reviewBody
  • Ìfiránṣẹ́ kan tí a gbé sórí Facebook ní orílẹ̀dè Nàìjíríà sọpé Bola Tinubu ti nípé òhun kò ní lè wá síbi ìtàkùrọ̀sọ àwọn olùdupò ààrẹ tí ilé-iṣẹ́ òkèèrè CNN , tí ó ń gbé ìròyìn jáde ṣonígbọ̀wọ́ ẹ̀ nítorí àìlera rẹ̀. Tinubu ni olùdupò ààrẹ lábẹ ẹgbẹ́ òṣèlú tí All Progressives Congress ní ètò ìdìbò gbogboògbò ti orílẹ̀dè Nàìjíríà, tí ọdún 2023 Ìfiránṣẹ́ tí a gbé síta ní ọjọ́ kaarùndínlógún oṣù keje ọdún 2022 kà báyìí: Ara mi ò yá, mi ò ní wá síbi ìtàkùrọ̀sọ àwọn olùdupò ààrẹ tí CNN ṣonígbọ̀wọ́ ẹ̀ – Tinubu kọ ìtàkùrọ̀sọ àwọn olùdupò ààrẹ ti CNN. A rí irú ìfiránṣẹ́ yìí lórí Facebook ní ibí , ibí àti ibí . Ṣùgbọ́n ṣé Bola Tinubu so ọ̀rọ̀ yìí? A ṣe ìwádìí . Kò sí èrí wípé ó so ọ̀rọ̀ náà Ìfiránṣẹ́ orí Facebook yìí kò sàlàyé ìgbà àti ibi tí Tinubu ti sọ ọ̀rọ̀ náà. A wo àwọn ohun tí wọ́n ti tẹ̀ jáde látorí orúkọ ìdánimọ̀ Tinubu tí ó ní àmì àrídájú lórí Twitter àti webusite rẹ̀, a kò rí èrí ọ̀rọ̀ náà níbẹ̀. Àtipé, kò sí ìròyìn tí ó ti ọwọ́ àwọn oníròyìn tí ó ṣe gbàgbọ́ ní orílẹ̀dè Nàìjíríà àti òkèèrè pé ó sọ ọ̀rọ̀ yìí, léyìí tí ó yẹ kí ó ṣẹlẹ̀ tí ó bá jẹ́ wípé òótó ni. CNN kò tíì ṣonígbọ̀wọ́ ìtàkùrọ̀sọ tó ní ṣe pẹ̀lú ìdìbò láti ìgbà tí wọn ti bẹ̀rẹ̀ iṣé ní orílẹ̀dè Nàìjíríà ní ọdún 2016. CNN ṣe ìfilọ́lẹ̀ onírúurú-ọ̀nà tí wọ́n yíò máa gbà ṣe iṣẹ́ wọn ní ìpínlẹ̀ Èkó, lórílẹ̀dè Nàìjíríà ní ọdún 2016, ṣùgbọ́n wọn kò tíì ṣonígbọ̀wọ́ ìtàkùrọ̀sọ fún àwọn olùdupò ààrẹ ní orílẹ̀dè Nàìjíríà ní àsìkò tí à ń jábọ̀ yìí. Nígbà tí a ṣe ìwádìí síwájú si lóri webusite CNN àti orúkọ ìdánimọ̀ rẹ̀ lóri Twitter nípa dídá ọjọ́ ìtàkùrọ̀sọ, a kò rí ohunkóhun tó jọ bẹ́è. Àtipé, ìtàkùrọ̀sọ ìdìbò máa ń wáyé ní àárín ìgbà tí àjọ Independent National Electoral Commission fàyè gba àwọn olùdíje láti ṣe ìpolongo. Ìpolongo àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú fún ìdìbò ipò ààrẹ àti ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin yíò bẹ̀rẹ̀ lójúlówó ní ọjó kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹsan odún 2022 tí yíò sì wá sí òpin ní ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kejì ọdún 2023. Àwọn oníròyìn orílẹ̀dè Nàìjíríà àti ilẹ̀ òkèèrè yíò ti gbe jáde tí ó bá jẹ́ pé òótọ́ ni ìtàkùrọ̀sọ àwọn olùdupò ààrẹ ti orílẹ̀dè Nàìjíríà tí CNN sonígbọ̀wó ẹ̀ yíò wáyé ní tòótọ́. (vi)
?:reviewRating
rdf:type
?:url