PropertyValue
?:author
?:datePublished
  • 2023-01-11 (xsd:date)
?:headline
  • Rárá, ọ̀gágun tí ó jẹ́ olórí orílẹ̀dè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀rí Babangida kò tweet pé òhun fọ̣wọ́sí bí Obasanjo ṣe fòntè lu Obi olùdíje fún ipò ààrẹ (vi)
?:inLanguage
?:itemReviewed
?:mentions
?:reviewBody
  • NÍ ÈDÈ KÚKÚRÚ : Tweet kan tí ó ń káàkiri ní orí Facebook ń fihàn pé ògágun tí ó jẹ́ olórí orílẹ̀dè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀rí sọpé òhun bu ọlá fún ààrẹ tẹ́lẹ̀rí Olusegun Obasanjo bí ó ṣe fòntẹ̀ lu Peter Obi olùdíje dupò ààrẹ lábé ẹgbẹ́ òṣèlú Labour. Ṣùgbọ́n tweet ọ̀hún wá látorí àkántì tí ó ń lo orúkọ ológun ọ̀hún lórí Twitter. Ọ̀gágun Olusegun Obasanjo yíò jẹ́ àgbà àti olórí tòótó tí wọn yíò máa bọlá fún títí láí bẹ́ẹ̀ sì ni yíò jẹ́ ọ̀gá láàrín àwọn ológun, báyìí ni tweet tí wọ́n tẹ̀ síta ní ọjọ́ kẹta oṣù kínní ọdún 2023 ṣe kà . Kò sí ògágun tí ó ń sìn lọ́wọ́ láàrín àwọn ológun ti orílẹ̀dè Nàìjíríà tí ó darapọ̀ mọ wọn sájú ọdún 1982. Ní ìgbà yẹn Obasanjo ti parí iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ológun, Mo bọlá fun púpọ̀, pẹ̀lú ìfọwósí rẹ̀. Tweet òhún wá látorí Twitter àkántì tí ó lórúkọ Ibrahim B. Babangida tí ìdánimọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ @General_Ibbro. Ibrahim Babangida jẹ́ ògágun télèrí lẹ́ni tí ó jẹ́ adarí orílẹ̀dè Nàìjíríà lábẹ́ ìjọba ológun láàrín ọdún 1985 sí ọdún 1993 Olusegun Obasanjo jẹ́ ààrẹ orílẹ̀dè òhún láàrín ọdún 1999 sí ọdún 2007 tí ó sì jẹ́ ẹni tí ó gbajúmọ̀ nínú ètò òṣèlú tirẹ̀. Ní ọjọ́ kínní oṣù kínní ni ó fọwọ́ mú Peter Obi ti ẹgbẹ́ òṣèlú Labour gege bi eni ti o je aayo re fun aare orilede Naijiria ninu eto idibo, ti o maa waye ní ọjọ́ karùndínlọ́gbon oṣù kejì. Síkírínísọọ̀tì tweet ọ̀hún ni wọ́n gbé sórí Facebook ní ibí , ibí , ibí ati ibí . Ṣùgbọ́n ṣé òótọ́ ni Babaginda tweet pé òhun bọlá fún Obásanjọ́ bí ó ṣe fọwọ́sí Obi? A ṣe ìwádìí. ‘Onírọ́ ni àwọn tí ó wà nídi gbólóhùn tí wọ́n gbé sórí Twitter’ Àpèjúwe tí ó wà lórí ojú ìwé @General_Ibbro ń tọ́ka sí pé àkántì tí ó ń farawé ọ̀gágun ọ̀hún ni. Ṣùgbọ́n eléyìí kò ní kí àwọn èèyàn kọ̀ láti dáhùn sí tàbí fi tweet ọ̀hún ránṣẹ́ sí àwọn míràn. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Babaginda ti sọpé òhun kò sí lórí òpó ìkànsíaraẹni kankan. Ní ọdún 2018 , Babaginda wá àwọn Twitter àkántì kan síta tí ó ń tẹ gbólóhùn jáde ní orúkọ rẹ ní àtakò. Àti pé Kassim Afegbua, tí ó jẹ́ agbẹnusọ fún ọ̀gágun ọhun ti sọ pé kìí ṣe òótọ́ ni Babaginda fọwọ́sí Obi. Kìí ṣe òótọ́, ẹ jọ̀ọ́ ẹ kọtí ikún sí ìròyìn ìfọwọ́sí. IBB kò ní àkántì lórí Twitter, ó sọ fún ìwé ìròyìn Nigerian Tribune . Tí ó bá fẹ́ sọ̀rọ̀, yíò jẹ́ nípasẹ̀ gbólóhùn tí ó bọwọ́lù, kìí ṣe Twitter. Onírọ́ ni àwọn tí ó wà nídi gbólóhùn orí Twitter. (vi)
?:reviewRating
rdf:type
?:url