?:reviewBody
|
-
Ìfiránṣẹ́ kan lóri Facebook ní orílẹ̀dè Nàìjíríà ní ọjọ kẹfà oṣù keje ọdún 2022 sọpé ọ̀gá ọlọ́pàá kan tí a dádúró, Abba Kyari ti sálọ sí orílẹ̀dè Australia lẹ́yìn tí àwọn jàndùkú agbébọn kan sàkọlù ẹ̀wọ̀n ibi tí wọ́n fi pamọ́ sí. Ìfiránṣẹ́ náà kà báyìí : Wákàtí lẹ́yìn àkọlù ẹ̀wọ̀n Kuje, A fojú ba Abba Kyari ní Australia Ìfiránṣẹ́ náà ni àwòrán méjì, àkọ́kọ́ tí ó dàbí síkírínsọtì láti inú fídíò kan, tí ó ṣàfihàn ọkùnrin kan tí ó ń wọnú ọkọ̀. Ìkejì jẹ́ ti Kyari nínú aṣọ olópàá. Ní ọjọ́ karùún oṣù keje , ní wọ́n sàkọlù ẹ̀wọn Kuje tí ó wà ní olú ìlú Abuja. Ní as̀ìkò àkọlù tí ó lé ní wákàtí yìí ni àwọn ẹlẹ́wọ̀n kan sálọ. Àwọn ẹgbẹ́ aṣèrùbàlú Islamic State West Africa Province (Iswap) ti nípé àwọn ni ó ṣe àkọlù òhún. Àjọ Nigerian Correctional Service ti tẹ orúkọ àti àwòrán mọ́kàndínlàádọ́rin ẹlẹ́wọ̀n tí ó sálọ síta. Ǹjẹ́ Kyari wà lára wọn, àtipé ṣe òótó ni ó sálọ sí Australia? A ṣe ìwádìí. ‘Kyari ò sálọ’ Kyari ni ẹni tí ó wà nínú àwòrán àkọ́kó, sùgbọ́n àwòrán ti tẹ́lẹ̀ ni. Ní oṣù kejì ni àjọ National Drug Law Enforcement Agency gbé àwòrán yìí gangan síta. Àjọ náà lo àwòrán náà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ní ìdojú kọ Kyari lẹ́yìn tí ó dúnàdúrà gbígbà sílè ògùn olóró cocaine tí wọ́n gbà lọ́wọ́ àwọn afunrasí oníṣòwò ògùn olóró kan. Ní ọjọ́ kẹfà oṣù keje , àjo Nigerian Correctional Service sọpé Kyari àti àwọn èyàn jànkàn jànkàn tàbí àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí ó gbajúmọ̀ tí wón wà ní ẹ̀wọ̀n Kuje kò sálọ. Umar Abubakar, ọ̀gá àgbà ní àjọ ọ̀hún, sọpé : Wọ́n wà ní ìhámọ́ lọ́wọ́ lọ́wọ́, láyọ̀ àti àlááfíà. Ọgbọ́n ẹ̀tàn jìbìtì Ìfiránṣẹ́ náà ní kí àwọn èèyàn ó tẹ link kan láti wo fídíò ibi tí wọ́n ní wọ́n ti rí Kyari ní Australia Ṣùgbọ́n link náà ń lọ sí orí site tí kò ní HTTP tó ní ààbò pẹ̀lú àròkọ tí ó ní àkọ̀rí : Ìjọba orílẹ̀dè Nàìjíríà ń tan ìròyìn èké ká: a kò sọpé IPOB jẹ́ ẹgbẹ́ aṣẹ̀rùbàlú, IPOB jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹgbẹ́ tí ó n pa òfin mọ́ ní Uk–UK yàgò fún Nàìjíríà. Àròkọ náà ń ṣini lọ́nà nítorí nínu ìròyìn kan tí wọ́n múdójúìwọ̀n tí a gbésíta lórí Daily Trust , ìjọba UK ti gbà pé Indigenous People of Biafra (Ipob) jẹ́ ẹgbẹ́ aṣẹ̀rùbàlú. Àròkọ náà kò sì ní ohunkóhun ṣe pèlú àwọn tí ó sálọ ní ẹ̀wọ̀n Kuje tàbí Abba Kyari.
(vi)
|