PropertyValue
?:author
?:datePublished
  • 2022-11-24 (xsd:date)
?:headline
  • Olùdíje dupò ààrẹ orílẹ̀dè Nàìjíríà Tinubu ń wo olùfigagbága rẹ̀ Obi lórí amóhùnmáwòrán inú ọkọ̀ òfurufú? Rárá, ìlú mọ̀ọ́ká kan ni ó tẹ àwòrán tí wọ́n ti ṣarúmọjẹ sí ránṣẹ́ (vi)
?:inLanguage
?:itemReviewed
?:mentions
?:reviewBody
  • NÍ ÈDÈ KÚKÚRÚ : Nínú àwòrán kan tí a ti sarúmọjẹ sí, Bola Tinubu ti ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress ni ó ti dàbí enipé ó ń wo Peter Obi ti ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party lórí amóhùnmáwòrán tí ó wà nínú ọkọ̀ òfurufú, ṣùgbọ́n nínú àwòrán tí ó jẹ́ ojúlówó, ojú amóhùnmáwòrán ọ̀hún ṣófo. Àwòrán kan tí a gbé sórí Facebook ni ó dàbí ẹnipé ó ń sàfihàn Bola Tinubu, olùdíje lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress ní ètò ìdìbò yíyan ààrẹ ti ọdún 2023 ní orílẹ̀dè Nàìjíríà, nínú ọkọ̀ ojú òfurufú pé ó ń wo olùfigagbága rẹ̀ Peter Obi lórí amóhùnmáwòrán. Obi jẹ́ olùdíje lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party. Charles Oputa , tí ó jẹ́ olórin àti òsèré ni ó tẹ àwòrán ọ̀hún síta ní ọjọ́ kẹjo oṣù kẹwa ọdún 2022. Oputa ẹni tí àwọn ènìyàn mọ̀ sí Charly Boy, ní ẹ̀gbàrún lé ẹgbẹ̀dógún(13,000) omolẹ́yìn lórí Facebook . Àkọ́lé tí ó fi sí àwòrán ọ̀hún ni, Káàbọ̀ sílé arákùnrin, ọkùnrin tí ó yẹ ní wíwò nìyí. Àwọn olùdìbò orílẹ̀dè Nàìjíríà ṣetán láti yan ààrẹ wọn tuntun ní ọjọ́ karùndínlọ́gbòn oṣù kejì ọdún 2023 . Ṣùgbọ́n ṣé àwòrán náà fihàn pé Tinubu ń wo Obi lórí amóhùnmáwòrán nínú ọkọ̀ ojú òfurufú? Tinubu ń wòta láti fèrèsé ọkọ̀ ojú òfurufú Títọ pinpin àwòrán látèyìnwá lórí Google fihàn pé wọn ti sarúmọjẹ sí àwòrán náà. Èsì ìwádìí fihàn wípé ìbèrè oṣù kẹwa ni wọ́n ya àwòrán òhún nígbà tí Tinubu padà sí orílẹ̀dè Nàìjíríà lẹ́yìn ìgbà tí ó rìnrìnàjò lọ sí ilẹ̀ UK. Aṣo kan náà ni ó wọ̀ nínú àwọn àwòrán yókù. Nínú ojúlówó àwòrán náà, tí ẹgbẹ́ kan tí ó ń sàtìlẹyìn fún Tinubu gbé sórí Twitter ní ọjọ́ kẹfà oṣù kẹwa–ọjọ́ méjì kí Oputa tó gbé àwòrán sí orí Facebook– Tinubu ń wòta láti fèrèsé ọkọ̀ òfurufú. Ojú amóhùnmáwòrán tí ó wà níwájú rẹ̀ ṣófo. Nínú Ìròyìn kan nípa dídé padà rẹ̀ sí orílẹ̀dẹ̀ Nàìjíríà ní àwòrán tí ó jẹ́ ojúlówó yìí àti àwọn míràn tíwọ́n yà níbí ayẹyẹ tí wọ́n ṣe láti ki káàbọ̀. (vi)
?:reviewRating
rdf:type
?:url