PropertyValue
?:author
?:datePublished
  • 2022-07-22 (xsd:date)
?:headline
  • Àwọn ọjọ́ ètò ìdìbò orílẹ̀dè Nàìjíríà ti ọdún 2023 kò yípadà, ó lòdì sí ohun tí wọ́n sọ lóri àwọn òpó ìkànsíaraẹni (vi)
?:inLanguage
?:itemReviewed
?:mentions
?:reviewBody
  • INEC kéde àwọn ọjọ́ ètò ìdìbò gbogboògbò ti odún 2023, ìfiránṣẹ́ ní oṣù kéje ọdún 2022 tí a gbé sórí ẹgbé Facebook kan tí ó lé ní 280,000 èèyàn wà ni ó bèrè báyìí. Independent National Electoral Commission (Inec) ni àjọ tí ó ń ṣe alákóso ètò ìdìbò ní orílẹ̀dè Nàìjíríà. Ìfiránṣẹ́ náà sọpé ètò ìdìbò gbogboògbò ti orílẹ̀dè Nàìjíríà ti ọdún 2023 láti yan ààrẹ, igbá kejì aàrẹ, àti àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin kékeré àti ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà tí yíò wáyé ní ọjọ́ kẹjìdínlógún oṣù kejì ọdún 2023. Tí ti àwọn gómínà àti àwọn ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ yíò wáyé ní ọjọ́ kẹ́rin oṣù kẹ́ta ọdún 2023, ó sàfikún. A rí irú ìfiránṣẹ́ tí ó farapẹ́ èyí ní orí Facebook ní ibí , ibí , ati ibí . Ǹjé òótọ́ ni ètò ìdìbò tí ó ń bò lórílèdè Nàìjíríà yíò wáyé ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyìí? A ṣe ìwádìí. Ètò ìdìbò gbogboògbò ti orílẹ̀dè Nàìjíríà yíò wáyé gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti sètò rẹ̀ tẹ́lẹ̀ Ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kejì ọdún 2022 ni àjọ Inec ti gbé ìwé ìlànà àti ètò àwọn ohun tí ó yẹ ní ṣíṣe fún ètò ìdìbò gbogboògbò ti ọdún 2023 sí orí ayélujára. Nínú rẹ̀ ni àwọn ọjọ́ àwọn ìgbésẹ̀ tí ó ṣe gbòógì tí yíò wáyé sáájú ètò ìdìbò àti ètò ìdìbò fún ra rẹ̀ wà. Ìwé ìlànà òhún fihàn wípé ìdìbò yíyan ààrẹ àti àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ asòfin (kékeré at̀i àgbà) yíò wáyé ní ọjọ́ káàrùndínlọ́gbọ̀n oṣù kejì ọdún 2023. Ìdìbò yíyan gómínà àti àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ yíò wáyé ní ọjọ́ kọkọ̀nlá oṣù kẹ́ta. Ìfiránṣe ̣́ orí Facebook yìí kò mẹ́nu ba ìgbà àti ìdí tí àjọ Inec fi yí àwọn ọjọ́ gbòógì wònyìí padà lóri kàléndà ètò ìdìbò. A wo webusite àti àwọn òpó ìkànsíaraẹni ti àjọ Inec ṣùgbọ́n a kò rí ibi tí wọ́n ti mẹ́nu ba ọjọ́ ìdìbò tuntun. Àwọn oníròyìn ìbílẹ̀ yíò ti gbé ìròyìn ìyípadà pàtàkì báyìí tí ó bá jé òótó àmó a kò rí èrí pé wọ́n ṣe èyí. Irú ìròyìn tí kò lóòtó nínú báyìí lè mú kí àwọn olùdìbò sọ ẹ̀tọ́ won láti dìbò yan ẹni tí ó wù wọ́n nù, àti láti kópa nínú ìjọba tiwa n tiwa. (vi)
?:reviewRating
rdf:type
?:url