?:reviewBody
|
-
NÍ ÈDÈ KÚKÚRÚ : Lẹ́yìn ìgbà tí Peter Obi olùdíje dupò ààrẹ kọ̀ láti yojú sí olùdíje dupò gómínà Beatrice Itubo nígbà tí ó sàbẹ̀wò sí ìpínlẹ̀ Rivers, ni àwọn tí ó ń gbé ìròyìn tí kò lóòtọ́ nínú bá mú iṣẹ́ wọn lójú pálí. Ṣùgbọ́n ṣe ni wọ́n sọpé ara Itubo kò yá nígbà náà, àti wípé kò sí ẹ̀rí pé ó sọpé òhun yíò kó àwọn ọmọ ẹgbẹ́ jọ láti tako Obi. Àtẹránṣẹ́ kan tí ó ń káàkiri lórí Facebook ń sọ pẹ̀lú àrídájú pé Beatrice Itubo, olùdíje dupò gómínà lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour ní ìpínlẹ̀ Rivers tí ó wà ní apá gúúsù orílẹ̀dè Nàìjíríà, jẹ́jèé pé òhun yíò ṣiṣẹ́ láti tako Peter Obi tí ó jẹ́ olùdíje dupò ààrẹ nínú ẹgbẹ́ oṣ̀èlú kan náà. Orílẹ̀dè Nàìjíríà setán láti se ètò ìdìbò gboogbògbò ní ìbèrè ọdún 2023. Èmi yíò kó àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour tí ó wà ní ìpínlẹ̀ Rivers jọ láti tako ọ̀gbẹ́ni Peter Obi. -Comr Beatrice Itubo, olùdíje dupò gómínà lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour, ní ìpínlẹ̀ Rivers, ìkan lára àwọn àtẹ̀ránṣẹ́ náà ló kà báyìí . Ó sì fi àwòrán Itubo kun. Òrọ̀ tí kò lóòtó nínú yìí farahàn nínú àtẹ̀ránṣẹ́ dósìnì lórí Facebook àti Instagram. Àwọn àpẹ̀ẹrẹ rẹ̀ nìyí ní ibí , ibí , ibí , ibí , ibí , ibí , ibí , ibí , ibí , àti ibí . Ọ̀rọ̀ náà bẹ̀rẹ̀ síní tàn ká lẹ́yìn tí Obi, ìkan lára àwọn aṣíwájú nínú ìdíje dupò ààrẹ, wọ́n fi ẹ̀sùn kàán wípé ó kọ̀ láti yọjú sí Itubo nígbà tí ó sàbẹ̀wò sí ìpínlẹ̀ Rivers. Gómínà ìpínlẹ̀ Rivers lọ́wọ́lọ́wọ́ Nyesom Wike, ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party (PDP), fìwé pe Obi síbi ìfilọ́lẹ̀ afárá ọlọ́nà Nkpolu-Oroworokwo tí wọ́n ṣẹ̀ kó parí ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kọkànlá ọdún 2022. Àwọn aláríwísi ti bú Obi pé kò yọjú sí Itubo ní ìgbà tí ó wà ní ìpínlẹ̀ Rivers. Wọ́n sọpé ṣeni ara Itubo kò yá ní ìgbà náà. Obi bẹ Itubo nínú àsopò tweet kan tí ó sì sọpé Àìmómò tó wáyé nítori àìsàkíyes̀í tí ó sì sọpé òhun kò mọ̀ wípé ó ń ṣàárẹ̀. Ẹ̀sùn pé ó ń fi ipò gómínà wá ipò ààrẹ Wọ́n tún fi ẹ̀sùn kan Obi wípé ṣe ni ó ń fi ànfààní ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ láti gbégbá orókè nínú ètò ìdìbò yan gómínà ní ìpínlẹ̀ náà ṣe pàṣípààrọ̀ fún ìgbárùkùtì Wike ní ìdíje dupò ààre ̣rẹ̀. Wike ti bẹ Obi láti sọ fún àwọn tí ó ń sàtìlẹyìn fun pé ẹgbẹ́ òṣèlú Labour kò lè borí ẹgbẹ́ òṣèlú PDP nínú ètò ìdìbò yan gómínà ní ìpínlẹ̀ Rivers àti pé ó ṣe ìlérí láti gbárùkù ti Obi lórí ìpolongo rẹ̀. Obi gba ìfilọ̀ òhún nígbà tí ó sọpé : Ìwọ [Wike] mọ̀ pé ìwọ ni alákóso. A ò ní bá ọ jà; enikẹ́ni tí ó bá bá ọ j̀a kò mọ ǹkan tí ó ń ṣe. Èmi ò ní danwò. Mò ń bẹ̀ ó, fún wa ní àpapọ̀ a ó sì fún o ní ìpínlẹ̀. Ṣùgbọ́n ṣé Itubo jéjèé pé òhun yíò mú kí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ó tako Obi? Ọ̀rọ̀ Itubo yàtọ̀ sí ohun tí ó wà nínú ọ̀rọ̀ àgbàsọ náà Àwọn àtèránṣé onírurú ọ̀hún kò sọ ní kíkún nípa ibi àti ìgbà tí Itubo sọpé òhun yíò tako òbí ní ìpínlẹ̀ Delta. Àì sí ọ̀rọ̀ kíkún yìí jẹ́ àmì pé ọ̀rọ̀ náà kò ríbí wọ́n ṣe sọ. Àwọn oníròyìn lórílẹ̀dè Nàìjíríà ti gbé ìròyìn síta nípa àwọn orísirísi ìsẹ̀lẹ̀ àìpẹ́ tí ó níṣe pẹ̀lú ìdíje dup̀o Obi , léyìí tí ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ sí Itubo jẹ́ ìkan. Ṣùgbọ́n kò sí iĺe iṣé oníròyìn tí ó dántọ́ tí ó gbé ìròyìn síta pé Itubo ní ètò láti tako Obi. Nínú ọ̀rọ̀ tí ó tẹ̀ jáde fún gbogbo èèyàn láti kà, Itubo kò fi béè kọbi ara sí ọ̀rọ̀ wípé Obi fi ìlàkàkà rẹ̀ láti di gómínà ṣe pàṣípàrò tí kò sì ní sàtìlẹyìn fun ní ìdìbò yíyan gómínà tí ó wà ní wájú. Gbólóhùn kan tí Asim Adams, agbenusọ fún ìgbìmọ̀ ìpolongo Beatrice Itubo tẹ̀ síta látorí orúkọ ìdánimọ̀ Itubo lórí Facebook ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kọkànlá ọdún 2022 , sọpé Obi sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àkàwé àti àfiwé nígbà tí ó dáhùn sí ìfilọ̀ Wike. Ó jẹ́ ohun tó bani lọ́kàn jẹ́ pé, àwọn kan gbà pé ọlọ́lájùlọ Peter Gregory Obi ti pa Beatrice Itubo àti àwọn olùdíje dupò míràn nínú ètò ìdìbò tí ó ń bọ̀ tì níbí wọ́n ṣe túmọ̀ àwọn àkàwé àti àfiwé wònyí... kò sí ohun tó jọ bẹ́è, gbólóhùn náà kà báyìí . Ẹ fi ọkàn balẹ̀, ohun tí ó ní lọ́kàn láti sọ kò ju ǹkan tí ó sọ lọ, a ti rí ìdánilójú látọ̀dọ̀ orísun àti alásẹ tí ó pegedé pé ọ̀rọ̀ ẹnu lásán ni tí ò kọjá pé ó sọ́ bí ìgbà tí ọ̀rẹ́méjì bá ń dáwàdà ....ẹ máa fi ọkàn sí ìtumò kítumọ̀ míràn tí ó lòdì sí èyí. Kò sí èrí lórí orúkọ ìdánimọ̀ Itubo lórí Twitter pé ó ń tako Obi lọ́wọ́lọ́wọ́. Ó sọfún àwọn oníròyìn wípé ọ̀rọ̀ tí Obi sọ jẹ́ gbólóhùn òṣèlú. Ó fikun pé Obi tí èmí mọ̀ lọ́gbón jù yẹn lọ. Ọ̀rọ̀ àgbàsọ òhún kò ní ẹ̀rí láti gbèé ní ìdí.
(vi)
|