?:reviewBody
|
-
NÍ ÈDÈ KÚKÚRÚ : Nínú ọ̀rọ̀ àgbàsọ tí ó ń káàkiri lórí òpó ìkànsíaraẹni, olùdíje dupò ààrẹ lábẹ́ African Action Congress ti sèlérí wípé àwọn akẹ́ẹ̀kọ́ unifásitì yíò ma gba ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọrun naira ní sáà kọ̀ọ̀kan tí òhun bá di ààrẹ. Ṣùgbọ́n kò sí ẹ̀rí wípé Omoyele Sowore sọ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀. Gẹ́gẹ́ bi àtẹránṣẹ́ orí Facebook kan ṣe sọ, olùdíje dupò ààrẹ orílẹ̀dè Nàìjíríà Omoyele Sowore ṣe ìlérí láti fún àwọn akẹ́ẹ̀kọ́ unifásitì ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ̣ọgọ́rin naira (US$230) ní sáà kànkan tí ó bá lè di ààrẹ. Àtẹ̀ránṣé ọ̀hún ní àwòrán Sowore nínú, ó sì kà báyìí : Àwọn akẹ́ẹ̀kọ́ unifásitì yíò ní ẹ̀tọ́ sí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọrun naira tí mo bá lè wọlé – AAC, Sowore. Sowore jẹ́ olùdíje dupò ààrẹ lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú African Action Congress (AAC) nínú ètò ìdìbò gbogboògbò tí yíò wáyé lórílẹ̀dè Nàìjíríà ní ọdún 2023. Ìpolongo òṣèlú fún ètò ìdìbò ti bẹ̀rẹ̀ lójúlówó ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹsan ọdún 2022, ní ìlànà pẹ̀lú ètò ti àjọ tí ó ń rí sí ètò ìdìbò Independent National Electoral Commission gbé kalẹ̀. A rí ọ̀rọ̀ àgbàsọ tí wọ́n nípe Sowore ló sọ, ní orí Facebook ní ibí , ibí àti ibí . Ǹjẹ́ Sowore ṣe ìlérí yìí? A ṣe ìwádìí. Kò sí èrí ọ̀rọ̀ àgbàsọ náà Àtẹ̀jáde orí Facebook ọ̀hún kò sọ ìgbà àti ibi tí Sowore ó dàbí ẹnipé ó sọ ọ̀ṛọ̀ yìí. Àì sí àlàyé yìí maa ń tọ́ka sí wípe wọ́ní wọ́n pé tí ó ń káàkiri lórí òpó ìkànsíaraẹni kò ṣe ń gbàgbọ́. A kò rí èrí ọ̀rọ̀ náà nígbà tí a wo orí orúkọ ìdánimò Sowore tí ó ní àmì àrídájú lórí Twitter. Ọ̀rọ̀ àgbàsọ náà kò jẹyọ nínú ìròyìn àwọn oníròyìn ìbílẹ̀, léyìí tí kò yẹ kí ó rí be tí ó bá jẹ́ pé òótọ́ ni ó sọ ọ̀rọ̀ náà. Ní oṣù kẹfà, Sowore sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan nípa ìdaṣẹ́sílẹ̀ awọn olùkọ́ni ti ilé ẹ̀kó unifásitì ní orílẹ̀dè Nàìjíríà, nínú àtẹ̀léra tweets láti orí orúkọ ìdánimọ̀ rẹ̀ tí ó ní àmì àrídájú lórí Twitter. Ó rọ àwọn akẹ́ẹ̀kọ́ orílẹ̀dè Nàìjíríà láti Fi ìmọ̀ ṣọ̀kan àti fipá mú kí ìjọba ẹlẹ́gàn ó #fòpinsíìdaṣẹ́sílẹ̀ASUUníkíákíá. Sùgbọ́n a kò rí ẹ̀rí pé Sowore sọpé òhun yíò fún àwọn akẹ́ẹ̀kọ́ unifásitì ní owó tí òhun bá wọlé gẹ́gẹ́ bi ààrẹ.
(vi)
|