?:reviewBody
|
-
NÍ ÈDÈ KÚKÚRÚ : Nínú àtẹ̀jáde kan tí ó ń kákìri lórí àwọn òpó ìkànsíaraẹni ni orílẹ̀dè Nàìjíríà, ó dàbí pé ààrẹ orílẹ̀dè Nàìjíríà télèrí Olusegun Obasanjo fọwọ́sí kí olùdíje dupò ààrẹ lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC Bola Tinubu di ààrẹ. Sùgbọ́n kìí ṣe òótọ́ ni ó so ọ̀rọ̀ tí wọ́n tẹ̀ yìí, òfútùfẹ́ẹ̀tẹ̀ s̀i ni ìfọwọ́sí ọ̀hún. Síkírínsọọ̀tì kan tí ó ń káàkiri lóri Facebook léyìí tí ó ní ọ̀rọ̀ kan tí ó dàbí ẹnipé ó ti ẹnu ààrẹ ẹ̀ méjì lórílẹ̀dè Nàìjíríà Olusegun Obasanjo , fọwọ́sí kí Bola Tinubu ó jẹ ààrẹ tí ó kàn lórílẹ̀dè Nàìjíríà. Tinubu jẹ gómínà tẹ́lẹ̀rí ní ìpínlẹ̀ Èkó tí ó wà ní apá Gúúsù-ìwọ̀-oòrùn orílẹ̀dè Nàìjíríà àti olùdíje lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú tí ó wà níjọba lọ́wọ́, All Progressives Congress . Ọ̀rọ̀ tí ó tẹnu jáde tí ó wà nínú Síkírínsoọ̀tì ọ̀hún, léyìí tí ó ní àwòrán Obasanjo àti Tinubu nínú kà báyìí: Èmi kìí ṣe olóṣèlú, ológun tí a ṣe ní ọ̀ṣọ́ ni mí, ọ̀gágun ni mí. Tí e bá ń wá olóṣèlú tí ó kúnjúwọ̀n ẹ lọ sí Èkó ní Bourdillon, e máa níbẹ̀. Tinubu ń gbé ní ọ̀nà Bourdillon tí ó wà ní Ikoyi, ní ìpínlẹ̀ Èkó, léyìí tí ó jẹ́ agbègbè tí àwọn ọlọ́rọ̀ ń gbe ́ . Lẹ́yìn tí ó dàbí ẹnipé ó sọpé ó kù díè kí òhún da ìjọba àti ìpínlẹ̀ [Bola] rú wọ́n nípé Obasanjo sọpé Tinubu yè nítorí pé ó ní ọ̀pá tí ó fi ń pidọ́n lọ́wọ́. Mo sì lérò wípé yíò ní ànfààní láti lo ọ̀pá tó fi ń pidọ́n yìí káàkiri orílẹ̀dè Nàìjíríà. Obasanjo sin orílẹ̀dè Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bi adarí ìjọba ológun láàrín ọdún 1976 àti 1979 tí ó sì jẹ́ ààrẹ orílẹ̀dè Nàìjíríà láàrín ọdún 1999 sí 2007, Ó darí ẹgbẹ́ òsèlú People’s Democratic Party. Síkírínsọọ̀tì tí wọ́n fi léde ní ọjọ́ keje oṣù kẹwa ọdún 2022, ni wọ́n tẹ̀ jáde ní ibí àti ibi ́ . Ṣùgbọ́n, ṣé Obasanjo ṣàpèjúwe Tinubu gẹ́gẹ́ bíi olóṣèlú tí ó kúnjúwọ̀n tí ó ní ọ̀pá tí ó fi ń pidọ́n lọ́wọ́? Obasanjo: ‘Irọ́ àti èké ni’ Obasanjo ti sọ wípé òhun kò fọwọ́sí Tinubu nínú ọ̀rọ̀ tí ó fi léde tí agbẹnusọ ààrẹ orílẹ̀dè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀rí náà, Kehinde Akinyemi bọwọ́ lù. Nínú ọ̀rọ̀ tí wọ́n tẹ̀ síta tí wọ́n fi ṣọwọ́ sí Africa Check, Obasanjo sọpé: Ológun nìkan ni ó máa ń kó àwọn ènìyàn bí wọn ṣe lè jẹ́ adarí rere yálà fún ènìyàn tàbí àwọn ohun èlò. Nítorí náà èmi kò lè fẹnu tẹ́mbẹ́lú òṣèlú tí ó jẹ iṣé ọlọ́lá tí kò ní ìlànà ìdánilẹ́kọ tó lágbara. Èyí jẹ́ irọ́ àti èké. Àwọn ilé-iṣé oníròyìn ti gbé àtẹ̀jáde ọ̀hún náà, tí ó ń bẹnu àtẹ́ lu ọ̀rọ̀ wípé Obasanjo fọwọ́sí kí Tinubu ó di ààrẹ orílẹ̀dè Nàìjíríà. Irọ́ ni.
(vi)
|