?:reviewBody
|
-
Ẹ̀yà àwòrán kan tí ó ń káàkiri lórí Facebook ní orílèdè South Africa àti Nàìj́iríà ni ó ń ṣe ìkìlò fún àwon olólùfẹ́ bisikí. Ó sopé bisikí tí ó ń jẹ́ crunches tí wọ́n kó wọlé láti South Africa wá sí orílèdè Nàìjíríà ni ó ti ‘pa máàrúnlélógójì èèyàn’ tí kẹ̀míkà tí ó lè ṣekú pani wà nínu rẹ̀. Nínú ẹ̀yà àwòrán ọhun, tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí Africa Check lórí WhatsApp ní oṣù kejì ọdún 2022, ni àwọn fótò bisikí ọ̀hún, àwòrán ọmọdé kan tí ó dàbí ẹnipé ara rẹ̀ so gídi gìdi, àti àwòrán orí ẹ̀yà kan tí ó jọ ènìyàn sùgbọ́n tí kìí ṣe ti ènìyàn tí kòkòrò bò. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú ẹ̀yà àwòrán náà kò fihàn wípé ìbásepọ̀ wà láàrín jíjẹ bisikí ọ̀hún àti àwòrán náà, ohun tí wọ́n ń gbìyànjú àti so ni wípé – kúkísì náà lè pani! Ṣùgbọ́n, ṣé òótó ni? Crunches Creams kò wá láti orílèdè South Africa Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ wípé ọ̀rọ́ tí ó wà nínú ẹ̀yà àwòrán náà mẹ́nuba bisikí tí a mọ̀ sí crunches tí ó sì dáàbá pé kí a wá crunches biscuits, lóri google, ọ̀rá bisikí tí ó fihàn nínú ẹ̀yà àwòrán náà ni orúko rẹ̀ ń jẹ́ Fox’s Crunch Creams. Àwọn ọmọ orílèdè South Africa tí ó wà ní ọ́fíìsì wa sọwípé àwọn ò mọ bisikí tí orúkọ ré ń jẹ́ Fox. Èyí jẹ́ àmì àkọ́kọ́ wípé ó lè jẹ́ òrọ̀ ẹ̀tan. A wá orúkọ ọ̀hún lórí Google, a rí ilé-isé Fox’s Biscuits tí ó ń ṣẹ̀dá Fox’s Golden Crunch Creams , tí ó kalẹ̀ sí ilẹ̀ UK. Bí ó tilẹ̀ jẹ́pé wón lè kó bisikí yìí gba orílèdè South Africa wọ orílèdè Nàìjíríà láti ilẹ̀ UK, a kòrò wípé eléyìí ṣeéṣe. Ó ṣeéṣe kí àwọn ọmọ orílèdè South Africa mọ bisikí tí afi óòtì àti àgbọn ṣe tí a ń pè ní crunches . Ṣùgbọ́n ilé ni a ti ma ń ṣe èyí jù , ní ọ̀pọ̀ ìgbà gẹ́gẹ́ bi ìlànà ìdáná ẹbí olúkálukú àmọ́ọ̀ tí kò jọ pé ó ṣeéṣe láti kó wọ ilẹ̀ ibòmíràn. Orí ètò kan lórí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán ni fótò náà ti wá A tẹ̀síwájú láti wá àwọn fótò tí ó kù nínú ẹ̀yà àwòrán náà. A kọ́kọ́ wá àwòrán ọmọ tí ara rẹ̀ lé gídigìdi àti orí tí kòkòrò bò tí a fi ọgbọ́n gbé le lórí, ṣùgbón a kò rí ǹkan kan. Àmóò, nígbà tí a gé fótò orí náà sọ́tọ̀, ti a sì wa fótò orí ọ̀hún nìkan, a rí àwọn fótò irú rè tí ó hàn kedere ju fótò náà lọ, nínú fótò èyí tí ó hàn kedere ni a ti ri wípé ogúnlọ́gọ̀ eyín ọmọ ènìyàn ni ó bo orí náà. Àwòrán náà tí èròngbà rẹ̀ ni láti pani ní ẹ̀rín ni wọ́n ti tẹ̀ ránṣẹ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, pẹ̀lú àbá pé kí àwọn òbí fihan àwon ọmọ wọn tí wọ́n bá béèrè bí iwin eléyín seŕi. (Ìkìlọ̀: eléyìí lè fa àlákàlá.) Ìwádìí díẹ̀ tí a ṣe si lórí ẹ̀rọ ayélujára fihàn wípé fótò náà jẹ́ ti ẹ̀dá kan nínú eré ìtàn àròsọ tí àkólé rẹ̀ ńjé Channel Zero: Candle Cove , lórí ẹ̀ro amóhùmáwòrán ní ọdún 2016. Ojú tí ó ń ba ni lérù ọ̀hún kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú jíjẹ bisikí crunchy tàbí irú míràn. Ẹ̀tàn àtijọ́ Lẹ́yìn ìgbésẹ̀ wònyí tí a ti gbé a ti ń rí ìdánilójú wípé ẹ̀yà àwòrán náà kò ní ìpìnlẹ̀ kan ní pàtó, a wá crunches biscuits, gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀ránṣẹ́ náà ṣe ní kí àwọn tí ó ń kàá ṣe. Ó kà báyìí ̀: Tí o kò bá gbàgbó wá orí Google fún àlàyé kíkún ‘crunches biscuits’ gba ẹ̀mí là, bí mo ṣe gba tìrẹ là. Ohun tí ó jásí niwípé orísirísi àpẹẹrẹ àtẹ̀ránsẹ́ yìí wá gbòde kan. Irú rẹ̀ kan ni a tè ránsẹ́ lórí òpó ìkànsíaraẹni kan ní orílèdè Nàìjíríà, pèlú ìlànà ìdáná fún crunches. A ri wípé ìwé ìròyìn Northern Natal News, ní orílèdè South Africa ní ọdún 2016 ni ó sàfihàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀tàn. Ìwé ìròyìn náà fi hàn kedere: kò sí bisikí crunches tí ó ní májèlé nínú, tí ó ń ṣekú pa àwọn ará ìlú. Ojú ìwé wẹ́ẹ̀bù ti SYY Hoax Analyzer náà tọ́ka si gẹ́gẹ́ bi ẹ̀tàn ní ọdún 2019. Ó kéré jù, ọdún 2016 ni àtẹ̀ránṣẹ́ yìí ti ń káàkiri, síbè síbẹ̀ ètànjẹ gbáà ni.
(vi)
|