?:reviewBody
|
-
Ààrẹ orílẹ̀dè Ghana Nana Akufo-Addo ti dásí ọ̀rọ̀ òṣèlú orílẹ̀dè Nàìjíríà nípa gbígba olùdíje dupò ààrẹ Bola Tinubu níyànjú láti fààyè gba olùfigagbága rẹ̀ Peter Obi. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àtẹ̀ránṣẹ́ tí ó ń káàkiri lórí Facebook láti ìgbà tí ó kù díè kí oṣù kẹfà ọdún 2022 ó wá sí òpin. Fún Peter Obi láàyè kí o sì lọ sètójú àilera ara rẹ – Ààrẹ Ghana kọ̀wé sí Tinubu, ojúlówó àtẹ̀ránṣẹ́ náà ló kà báyìí. Àwọn irú àtẹ̀ránṣẹ́ òhún míràn ni a rí ní ibí , ibí , ibí àti ibí . Ìdìbò láti yan ààrẹ orílẹ̀dè Nàìjíríà ni yíó wáyé ní ọjọ́ karùndínlógún oṣù kejì ọdún 2023. Tinubu, ọmọ àádọ́rin ọdún, olùdíje dupò ààrẹ lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress nígbà tí Peter Obi, ń díje dupò ààrẹ lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party . Orílẹ̀dè Ghana wà ní apá Ìwọ̀-oòrùn orílẹ̀dè Nàìjíríà tí ó wà ní Ìwò-oòrùn ilẹ̀ adúláwọ̀. Sùgbọ́n ṣé ààrẹ rẹ̀ kọ̀wé sí Tinubu láti fún Obi láàyè àti láti wá ìtọ́jú fún àìlera ara rè? A ṣe ìwádìi. ‘Irọ́ pátá gbáà àti ọgbọ́n àti dá wàhálà sílẹ̀’ Àwọn àtẹ̀ránṣẹ́ òhún kò ṣe àlàyé ní kíkún nípa ìgbà tí Akufo-Addo kọ̀wé sí Tinubu. Àti pé kò sí ìròyìn lẹ́tà náà látọwọ́ àwọn oníròyìn ti orílẹ̀de Nàìjíríà àti ilẹ̀ òkèèrè léyìí tí ó yẹ kí ó wà tí ó bá jẹ́pé òótó ni ó kọ lẹ́tà náà. Ní ọjọ́ kẹsan oṣù kẹjo, Akufo-Addo te ̣ síkírínsọọ̀tì ọ̀kan lára àwọn àtèránṣẹ́ náà síta látorí orúkọ ìdánimọ̀ rẹ̀ tí ó ní àmì àrídájú lórí Twitter tí wón fi òǹtẹ̀ FAKE lù. Nínú àwọn àsopọ̀ tweet mẹ́ta kan, ni ó ti sàpèjúwe ọ̀rọ̀ náà gẹ́gẹ́ bi èyí tí ó daniláàmú , tí ó jẹ́ irọ́ pátá gbáà, tí ó ní ọgbọ́n àti dá wàhálà sílẹ̀ , tí kò sì ní òótọ́ kan kan bí ó ti wù kó mọ nínú. Èmi ò kọ lẹ́tà tí ó jọbẹ́ẹ̀ sí olórí ẹgbẹ́ òṣèlú APC, tí kò dè ní sọ sími lọ́kàn láti kọ. Orílẹ̀dè Ghana àti Nàìjíríà ní àjọṣepọ̀ ọdún bọ́dún tí ó dánmọ́ran, tí ó lágbára, tí ìbáṣepò wọn sì dàbí ti arákùnrin méjì. Èmi kò ní dásí ọ̀rọ̀ abélé àti òṣèlú orílẹ̀dè Nàìjíríà, Akufo-Addo ko ̣ báyìí.
(vi)
|