PropertyValue
?:author
?:datePublished
  • 2023-01-11 (xsd:date)
?:headline
  • Rárá, Alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC tí ó wà lóri àléfà lọ́wọ́ ní orílẹ̀dè Nàìjíríà kò sọpé àjọ tí ó ń rísí èto ìdìbò kò lè fòpin sí bí àwọn tí kò tó dìbò ṣe ń dìbò (vi)
?:inLanguage
?:itemReviewed
?:mentions
?:reviewBody
  • NÍ ÈDÈ KÚKÚRÚ : Kò sí ẹ̀rí bí ó ti wù kó mọ pé Abdullahi Adamu, alága ẹgbẹ́ òṣèlu All Progressives Congress sọpé àjọ tí ó ń rí sí ètò ìdìbò ní orílẹ̀dè Nàìjíríà kò ní agbára láti má fàyè gba àwọn t́i kòì tí tó ọmọ ọdún méjìdínlógún láti dìbò, tàbí ó sọpé ará ìlú tí ò ní ẹ̀tó láti dìbò, ni wọ́n. Àgbà olóṣèlú kan ti sọpé àjọ tí ó ń rí sí ètò ìdìbò ní orílẹ̀dè Nàìjíríà kò ní àṣẹ láti má jẹ́ kí àwọn tí kòì tíì tó ọmọ ọdún méjìdínlógún ó dìbò nínú ètò ìdìbò tí orílẹ̀dè ọ̀hún tí ó ń bọ̀ lọ́nà. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ọ̀rọ̀ àgbàsọ kan tí ó ń káàkiri lórí Facebook láti ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ oṣù kínní ọdún 2023 ṣe sọ. INEC kò ní àṣe láti má fàyè gba àwọn tí ọjọ́ orí wọn kòì tó iye ọdún tí òfin làkalẹ̀, gbogbo wọn ni ó ma dìbò gẹ́gẹ́ bí ojúlówó ọmọ orílẹ̀dè yìí tí ó ní ẹ̀tọ́ láti dìbò, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ náà kà . Ọ̀rọ̀ náà ni wọ́n ní pé Alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC. tí ó jẹ́ Abdullahi Adamu , alága àgbà tí ẹgbẹ́ òṣèlu ́All Progressives Congress . Àwọn ọmọ orílẹ̀dè Nàìjíríà ti gbáradì láti dìbò yan ààrẹ wan tuntun, àwọn gómínà ìpínlẹ̀, àti àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ti ìpínlẹ̀ àti ti àpapọ̀ ní oṣù kejì àti oṣù kẹta. Gẹ́gẹ́ bí àjọ Inec ṣe sọ, tí ó jẹ Independent National Electoral Commission , àwọn ọmọ orílẹ̀dè Nàìjíríà tí kòì pé ọmọ ọdún kejìdínlógún tí òfin fàyègbà láti dìbò ni wọn kò ní gbà láàyè láti forúkọ sílẹ̀ láti dìbò tàbí tẹ̀ka lọ́jọ́ ìdìbò. Ṣùgbọn ṣé Adamu sọ báyìí ní tòótọ́? A ṣe ìwádìí Kò sí ìròyìn ọ̀rọ̀ tí ó lè fa inúnibíni yìí Ọ̀rọ̀ àgbàsọ ọ̀hún kò sọ ní pàtó ìgbà àti ibi tí Adamu ti sọ ọ̀rọ̀ tí wọn nípé ó sọ yìí. Àti pé kò sí ìròyìn kankan látọwọ́ àwọn oníròyìn ti orílẹ̀dè ọ̀hún pé ó sọ ohunkóhun tí ó ní ṣe pẹ̀lú àwọn olùdìbò tí ọjọ́ orí wọn kéré sí èyí tí òfin fàyègbà. Tí Adamu bá sọ irú ọ̀rọ̀ tí ó lè fa inúnibíni yìí, yío ti jáde nínú ìròyìn àwọn oníròyìn tí ó dángájíá. Ọ̀rọ̀ àgbàsọ yìí kìí ṣe òótọ́. Gẹ̣́́ge bí òfin àti ìlànà fún ṣíṣe ètò ìdìbò ti àjọ Inec, ìjìyà wà fún àwọn tí kòì tó ọjọ́ orí tí òfin fàyègbà àti àwọn tí kìí ṣe ọmọ orílẹ̀dè Nàìjíríà tàbí ẹni tí ó jí ìdánimọ̀ ẹlòmíràn lò tí ó sì wá láti dìbò. Kìí ṣe pé wọn kò ní jẹ́ kí wọ́n dìbò nìkan, ṣùgbọ́n wọn tún lè fi ọlọ́pà gbé wọn àti kí wọ́n bá wọn ṣẹjọ́. (vi)
?:reviewRating
rdf:type
?:url