PropertyValue
?:author
?:datePublished
  • 2022-03-31 (xsd:date)
?:headline
  • Rárá, Buhari kò ní kí àwọn ológun orílèdè Nàìjíríà ó mùra ogun (vi)
?:inLanguage
?:itemReviewed
?:mentions
?:reviewBody
  • Àwòrán kan tí ó ń káàkiri lórí Facebook ni ó fi hàn bí ẹnipẹ́ ààrẹ orílẹ̀dè Nàìjíríà Muhammadu Buhari ń sọ fún àwọn ológun orílẹ̀dè Nàìjíríà pé ẹ múra ogun. Àwòrán náà dàbí síkírínísotì tweet kan tí ó wá lá tọ̀dọ̀ @Mbuhari tí ó jẹ́ orúkọ ìdánimọ̀ re lórí Twitter . Tweet náà kà báyìí: A dúró ti Ukraine ní ìgbà ìṣòro yìí, léyìn ìgbà tí a ti bá ààrẹ Biden sọ̀rọ̀ lórí ìpinu rẹ̀, mo ti bá àwọn ológun mi sọ̀rọ̀ láti gbáradì fún ogun! À kò ní jé kí eléyìí lọ báyẹn. Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kejì ni orílẹ̀dè Russia kógun ja orílẹ̀dè tí ó tìí, Ukraine, láti ìgbà náà ni inúnibíni láàrín orílẹ̀dè méjèèjì yìí ti jọba lórí àkọ́lé àwọn ìròyìn tó kù káàkíri àgbáyé. Ṣùgbọ́n, ṣé Buhari tweet wípé òhún ní kí àwọn ológun ó gbáradì lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ààrẹ Joe Biden ti US sọ̀rọ̀? A ṣe ìwádìí. Kò sí èèrí wípé ààrẹ sọbẹ Ọjọ́ kínní oṣù kẹfà ọdún 2021 ni tweet tí ó kẹ́yìn wá látorí orúkọ ìdánimọ̀ tí ó ní àmì àrídájú tí ó sì jẹ́ ti Buhari, lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tí ìjọba àpapọ̀ gbẹ́sẹ̀ lé lílo Twitter ní orílẹ̀dè Nàìjíríà. Ọjọ́ kejìlá oṣù kínní ọdún 2022 ni ìjọba àpapọ̀ gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí lílo Twitter, ṣùgbọ́n láti ìgbà náà ni ààrẹ kò ti tweet. Àmìn míràn wípé síkírínísotì náà kìí ṣe ojúlówó nipé ó ní púpọ̀ àsìkọ ọ̀rọ̀, ní èyí tí irú rẹ̀ ò lè ṣẹlẹ̀ nínú ìbáraẹnisọ̀rọ̀ tí ó bá ti ọ́fíìsì ààrẹ wá. Kò sí ìròyìn irú ọ̀rọ̀ báyìí tí ó jẹyọ nínú ìròyìn àwọn oníròyìn ní orílẹ̀dè Nàìjíríà. Gbogbo ẹ̀rí fihàn wípé kò ní òótọ́ nínú. (vi)
?:reviewRating
rdf:type
?:url