PropertyValue
?:author
?:datePublished
  • 2022-12-09 (xsd:date)
?:headline
  • Kò sí ẹ̀rí pé olùdíje dupò ààrẹ lórílẹ̀dè Nàìjíríà Bola Tinubu sọpé òhun pàdánù àwọn ọmọ kílàsì òhun ní ogun abélé ti Biafra (vi)
?:inLanguage
?:itemReviewed
?:mentions
?:reviewBody
  • NÍ ÈDÈ KÚKÚRÚ : Olùdíje lábẹ́ APC Bola Tinubu ni wọ́n ti dá lágara pẹ̀lú ìbéèrè nípa àwọn ìwé ẹri re, Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n sọpé òhun ló sọ kò ní ẹ̀rí kankan láti gbèé nídìí. Ọ̀rọ̀ àgbàsọ kan tí ó ya ni lẹ́nu púpọ̀ tí wọ́n gbé sórí Facebook, ni wọ́n sọpé Bola Tinubu tí ó jẹ́ olùdíje lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú tí ó ń ṣè ìjọba lọ́wọ́lọ́wọ́ nínú ètò ìdìbò orílẹ̀dè Nàìjíríà ní ọdún tó ń bọ̀ ni ó sọbẹ́ẹ̀. Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àgbàsọ yìí ni àwòrán Tinubu níbi tí ó ti ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀, ó kà báyìí : Mo pàdánù gbogbo àwọn ọmọ kílàsì mi nínú ogun Biafra ~~Asiwaju Bola Ahmed Tinubu. Bola Tinubu ń díje lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress nínú ètò ìdìbò tí yíò wáyé ní oṣù kejì ọdún 2023. Ogun abélé orílẹ̀dè Nàìjíríà tí a tún mọ̀ sí ogun Nàìjíríà àti Biafra ni wọ́n jà láàrín ọdún 1967 sí 1970. Ó wáyé láàrín ìpínlẹ̀ kan ní apá gúúsù ìlà-oòrùn orílẹ̀dè Nàìjíríà tí ó fẹ́ yapa kúrò tí wọ́n pè ní Biafra àti ìjọba àpapọ̀ ti orílẹ̀dè Nàìjíríà, léyìí tí ó sokùnfa ikú ìṣirò mílíọ́nù kan ènìyàn. Àwọn ìbéèrè nípa ipele tí Tinubu kẹ́kọ̀ọ́ dé àti àwọn ìwé-ẹ̀rí rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1999 nígbà tí ó kọ́kọ́ gbápòtí fún ipò gómínà ní ìpínlẹ̀ Èkó. Ìpinnu rẹ̀ láti díje dupò ààrẹ ní ọdún 2023 ni ó túbò fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbéèrè nípa ìtan bí ó ṣe kẹ́kọ̀ọ́ , ọjọ́ orí rẹ̀, ẹni tí ó jẹ́ gangan àti ìlera rẹ̀. Festus Keyamo tí ó jẹ́ agbẹnusọ fún ìgbìmọ̀ ìpolongo APC nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ lórí amóhùnmáwòrán gbìyànjú láti dahùn lára àwọn ìbéèrè wònyí lọ́nà tí kò finí gbérí mọ́, ṣùgbọ́n ó dà bí ẹnipé àwọn ìbéèrè wònyí ṣì pàpà ń jẹyọ síbẹ̀. A rí irú ọ̀rọ̀ àgbàsọ ọ̀hún lórí Facebook ní ibí , àti ibí . Kò sí èrí ọ̀rọ̀ náà Àtẹ̀ránṣẹ́ orí Facebook òhún kò ṣe àlàyé ní kíkún nípa ìgbà àti ibi tí wọ́n ní Tinubu ti sọ ọ̀rọ̀ náà, Eléyìí jẹ́ àmì pé àtẹ̀ránṣẹ́ tí wọ́n gbé sórí òpó ìkànsíaraẹni jẹ́ irọ́. A wá orí orúkọ ìdánimọ̀ Tinubu tí ó ní àmì àrídájú lórí Twiter àti ojú ìwé wẹ́ẹ̀bù rẹ̀ a kò rí ẹ̀rí ọ̀rọ̀ náà. Àti pé, kò sí ìròyìn tí ó wá látọwọ́ àwọn oníròyìn ìbílè tí ó dántọ́, nípa ọ̀rọ̀ náà, léyìí tí ó yẹ kó wà tí ó bá jẹ́ pé òótó ni. Kò sí ẹ̀rí pé Tinubu sọpé gbogbo àwọn ọmọ kílàsì rẹ̀ ni ó kú nínú ogun abélé tí ó wáyé lórílẹ̀dè Nàìjíríà. (vi)
?:reviewRating
rdf:type
?:url