?:reviewBody
|
-
Fídíò ọkọ̀ ojú òfurufú kan tí kò ní ìyẹ́ mọ́ tí wọ́n ń gbé lọ ní òpópónà márosẹ̀ kan ni ó ń káàkiri ní orílẹ̀dè Nàìjíríà, tí àwọn kan sì ń sopé ṣe ni ọkọ̀ ojú òfurufú náà já lulẹ̀ ní pópónà kan tí ó súnmọ́ pápá ọkọ̀ òfurufú ti Murtala Muhammed ní ìlú Ikeja ní ìpínlẹ̀ Èkó. Àwọn ońiròyìn ti agbègbè díẹ̀ náà gbé ìròyìn yìí ní àsìkò tí ó ku díẹ̀ kí osù káàrún, ọdún 2022 ó parí. Ṣùgbọ́n kíni ìròyìn náà lẹ́kùnrẹ́rẹ́ Àwọn aláṣẹ bẹnu àtẹ́ lu ìròyìn ọ̀hún Federal Airports Authority of Nigeria (FAAN), ilé-iṣé ìjọba tí ó jẹ́ alákóso àwọn pápá ọkọ̀ ojú òfurufú tí ó ń powó wọlé bẹnu àtẹ́ lu ọ̀rọ̀ náà. FAAN nínú ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbé sóri Facebook ní ọjó kerìnlélógún, oṣù káàrún so fún àwọn ará ìlú wípé ẹ má gba ìròyìn tí ó ń káàkiri lórí àwọn òpó ìkànsíaraẹni nípa ọkọ̀ ojú òfurufú tí ó já lulẹ̀ ní pápá ọkọ̀ ojú òfurufú Ikeja gbọ́. Ẹni tí ó ni ọkọ̀ ojú òfurufú ọ̀hún ti tàá fún oníbàrà, tí ó ń gbe lọ sí ibi tirẹ̀. Lagos State Emergency Agency náà bẹnu àtẹ́ lu ìròyìn náà, wọ́n sọpé Ǹkan tí ó jọ béè kò sẹlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìwé-ìròyìn Punch ti gbe síta. Kò sí àmì ìjàmbá lára ọkọ̀ ojú òfurufú náà Ọkọ̀ ojú òfurufú tí ó wà nínú fídíò náà kò ní àmì ìjàmbá kànkan lára, bẹ́ẹ̀ sìni ó hàn wípé ṣe ni wọ́n yọ ìyẹ́ rẹ̀ bí ó ṣe yẹ kí wọ́n yọ́. Nínú àwọn àsopọ̀ tweet , amòye nípa iṣẹ́ ọkọ̀ òfurufú Daniel Dikio nípé bàlúù náà jẹ́ Airbus A319 , àti pé wọ́n ti yọ ìyẹ́ rẹ̀ sọ́tọ̀ bó ṣe tọ́. Eléyìí kò le è sẹlẹ̀ nínú ìjàmbá, Ìyọsọ́tọ̀ yìí jẹ́ àmì wípé wọn tú ba lẹ̀ ni. Kò sí ìbàjẹ̀ kànkan lára bàlúù náà, léyìí tí kò ní ṣaláì wáyé tí ọ̀rọ̀ bá rí bí wọ́n ṣe sọ. Mo ti sàtúnyẹ̀wò data súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ojú òfurufú mi ò sì rí ǹkan tí ó sàjèjì, àti wípé gbogbo àwọn bàlúù A320 tí ó ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́ ní orílèdè Nàìjíríà ni ó pé níye lẹ́yìn tí mo kà wọ́n, tweet Dikio ló kà báyìí.
(vi)
|