PropertyValue
?:author
?:datePublished
  • 2023-01-10 (xsd:date)
?:headline
  • Irọ́ ni ìpolongo ìgbani síṣẹ́ fún ètò ìdìbò 2023 ti àjọ INEC ti orílẹ̀dè Nàìjíríà (vi)
?:inLanguage
?:itemReviewed
?:mentions
?:reviewBody
  • NÍ ÈDÈ KÚKÚRÚ : Bí ó tilẹ̀ jẹ́pé àtẹ̀jáde ṣì ń káàkiri lórí àwọn òpó ìkànsíaraẹni ní orílẹ̀dè Nàìjíríà, àjọ tí ó ń rísí ètò ìdìbò lórílẹ̀dè náà kò gba àwọn èèyàn siṣẹ́ fún ètò ìdìbò gbogboògbò ti ọdún 2023 mọ́. Òótọ́ ni: Inec fẹ́ gba 1.4 millionu èèyàn síṣẹ́, àtẹ̀jáde kan tí a gbé sórí Facebook ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kejìlá ọdún 2022 ni ó kà báyìí . Àjọ Independent National Electoral Commission , àbí Inec ti orílẹ̀dè Nàìjíríà ń gba ni síṣẹ́ fún ètò ìdìbò gbogboògbò tó ma wáyé ní osù kéjì àti ìkẹ́ta ọdún 2023. Àtẹ̀jáde orí Facebook míràn kà báyìí : Forúkọ sílè fún ètò ìgbani síṣẹ́ INEC fún ètò ìdìbò gbogboògbò ti ọdún 2023. Òfin orílẹ̀dè Nàìjíríà ti ọdún 1999 ni ó ṣe àgbékalè Independent National Electoral Commission (INEC) láti ṣètò ìdìbò sí oríṣiríṣi ipò ní orílẹ̀dè yìí. Sùgbọ́n ṣé Inec ń gbani síṣé? A ṣe ìwádìí. Ìgbani síṣé èké Ní ọjọ́ kẹta ọdún 2023, Inec tẹ gbólóhùn jáde pé ìpolongo ìgbanisíṣẹ́ ọ̀hún jẹ́ èké. Kí àwọn ará ìlú ó fi sọ́kàn pé àjọ yìị́ kò gbani síṣẹ fún ètò ìdìbò gbogboògbò ọdún 2023 mọ́. Ọ̀nà ìforúkọ sílẹ̀ fún ètò ìgbanisíṣẹ́ òhún ti tì láti ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kejìlá ọdun 2022, gbólóhùn náà kà báyìí . Nínú àtẹ̀jáde tí Rotimi Oyekanmi, akọ̀wé àgbà fún ètò ìròyìn bọwọ́lù, ó sọpé ọ̀nà ìforúkọsílẹ̀ fún iṣé ọ̀hún wà ní sísí láti ọjọ́ kerìnlá oṣù kẹsan títí di ọjọ́ kerìnlá oṣù kejìlá àti pé àjọ náà kò gbani sísẹ́ mọ́. (vi)
?:reviewRating
rdf:type
?:url