PropertyValue
?:author
?:datePublished
  • 2022-07-21 (xsd:date)
?:headline
  • Rárá ilé ìgbìmò aṣòfin ìpínlẹ̀ Èkó kò fi òntẹ̀ lu òfin Sharia láti ran olùdupò ààrẹ orílèdè Nàìjíríà lọ́wọ́ (vi)
?:inLanguage
?:itemReviewed
?:mentions
?:reviewBody
  • Síkírínísotì webusite kan ní wọ́n tẹ̀ ránṣẹ́ lóri Facebook àti WhatsApp ní orílèdè Nàìjíríà ní àárín oṣù kéje ọdún 2022, tí wón so nínú rẹ̀ pé ìpínlẹ̀ Èkó ti fi òǹtẹ̀ lu kí wọ́n sàgbékalẹ̀ ilé ẹjó Sharia ní ìpínlẹ̀ òhún. Sharia jẹ́ òfin ẹ̀sìn Islam, tí àwọn Mùsùlùmí rí gẹ́gẹ́ bí àgbékalẹ̀ àṣẹ ọlórun tí ó sì di ètò ojúṣe fún àwọn onígbàgbọ́. Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Èkó ti fi òǹtẹ̀ lu òfin Sharia ní ìkọ̀kọ̀, lọ́nà lá ti jẹ́ kí àwọn ará òkè oya ó sàtìlẹ́yìn fún Tinubu, òrò tí ó wà nínu síkírínísotì náà ni ó kà báyìí. Ó tẹ̀síwájú: Àìnírètí Bola Tinubu ti wá dé góngó báyìí nígbà tí a rò wípé kò lè teríbia ju bí ó ti se télè fún àwọn ọ̀gá rẹ̀ lókè ọya. Tinubu ni olùdupò ààrẹ lábẹ ẹgbẹ́ òṣèlú tí ó wà lórí àléfà lọ́wọ́ ìyẹn All Progressives Congress ní ètò ìdìbò fún ipò ààrẹ ti orílẹ̀dè Nàìjíríà, tí yíò wáyé ní osù kejì ọdún 2023 Ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú s íkírínísotì ọ̀hún tún sopé ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínl̀ẹ fi òǹtẹ̀ lu àbá láti ṣàgbékalẹ ilé ẹj̣̣ọ́ Sharia ní bòúnkẹ́lẹ́ àti ní kíákíá tí yíò sì fàyègba òfin Sharia ní ìpínlẹ̀ Èkó léyìí tí gómínà ti bu ọwọ́ lù látìgbà náà. A rí irú ìfiránṣẹ́ náà níbò míràn lóri Facebook. Ǹjẹ́ ìròyìn yìí jẹ́ òótọ́ bí? A ṣe ìwádìí Iro gbaa ni wọ́n pe ọ̀rọ̀ náà Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Èkó ti sọ lóri Twitter ní ọjọ́ ketàlá oṣù keje wípé irọ́ gbáà ni ìròyìn ọ̀hún. Ọ̀rọ̀ ní kíkún látẹnu Setonji David tí ó jẹ alága ìgbìmọ̀ lórí àlàyé, ààbò àti ète, kà báyìí : A ti pe àkíyèsí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Èkó sí ìròyìn kan tí ó ní bákàn bàkàn nínú, tí kò sì ní ìpìnlẹ̀ tí ó ń káàkiri lórí àwọn òpó ìkànsíaraẹni, wípé ilé ìgbìmọ̀ ti fi òǹtẹ̀ lu òfin sharia lọ́nà láti jẹ́ kí àwọn ará òkè ọya ó sàtìlẹ́yìn fún Tinubu, olùdupò ààrẹ lábé ẹgbẹ́ òṣèlú APC. A kò bá má buyì fún ẹni tí ó kọ ọ̀rọ̀ ìkóríra yìí, ṣùgbọ́n láti fi ìdí òtítọ́ múlẹ̀, èrò ẹni tí ó kọ́ lásán ni, àti wípé irọ́ gbáà láti ọ̀fìn àpáàdì ni. David tún sopé ìlànà ṣíṣe òfin jẹ́ èyí tí ó hàn kedere sí àwọn ará ìlú: Wọn kò lè so àbá dòfin láì pe ìpàdé àwọn ará ìlú láti tẹ́tísi ní ìpínlẹ̀ Èkó. (vi)
?:reviewRating
rdf:type
?:url