?:reviewBody
|
-
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìfiránṣẹ́ lórí Facebook ni ó ń so wípé ààre African Development Bank , Akínwùnmí Adéṣínà, ń sàtìlẹyìn Bọ́lá Tinubu, ọ̀kan lára ó lé ní méjìlá olóṣèlú ní orílẹ̀dè Nàìjíríà tí ó ń gbìyànjú láti bọ́sípò ààre Muhammadu Buhari ní ọdún 2023. Àwọn àtẹ̀ránṣẹ́ náà, tí ó jáde ní oṣù kẹ́rin ọdún 2022, nípé Adésínà so wípé: Tí senator Bọ́lá Ahmed Tinubu bá lè mú kí ọrọ̀-ajé ìpínlè Èkó ṣe ipò káàrún ní ilẹ̀ adúláwọ̀ àti ìpínlẹ̀ tí ewu rẹ̀ kéré jùlọ̀ ní orílẹ̀dè Nàìjíríà, ó yẹ kí a mọ ohun tí ó máa ṣe gẹ́gẹ́ bíi ààrẹ orílẹ̀dè Nàìjíríà. Tinubu jẹ́ gómínà ìpínlẹ̀ Èkó ní ọdún 1999 sí 2007 tí ó sì jẹ́ olósèlú tí ó gbajúgbajà ní ìpínlẹ̀ náà àti ní ẹgbẹ́ òṣèlú All progressives congress síbẹ̀. Lẹ́yìn ìpàdé kan pẹ̀lú Buhari ní ọjọ́ kẹẹ̀wá oṣù kínní ọdún 2022, Tinubu fi ìpinu rẹ̀ hàn láti gbé àpótí dupò ààrẹ ní ètò ìdìbò gbogboògbò ní ọdún 2023. Sùgbọ́n, ǹjẹ́ Adéṣínà, tí ó jẹ́ mínísítà fún ètò ọ̀gbìn ní orílẹ̀dè Nàìjíríà ní ọdún 2011 sí 2015, ṣàtìlẹyìn Tinubu fún ipò ààrẹ? Ọ́fíìsì Adéṣínà bẹnu àtẹ́ lu ọ̀rọ̀ náà Ọ̀rọ̀ náà kọ́kọ́ káàkiri lórí èrọ ayélujára ní oṣù kínní ọdún 2022 , lẹ́yìn tí Tinubu kéde pé òhun fẹ́ díje dupò ààrẹ. Adéṣínà bẹnu àté lu ọ̀rọ̀ náa nígbà náà loun. Ìwé ìròyìn Guardian gbé ìròyìn síta ní ọjọ́ kejìlá ọdún 2022 wípé Victor Ọládòkun tí ó jẹ́ olùdámọ̀ràn àgbà lórí ìbáraẹnisọ̀rọ̀ fún Adéṣina, sọ wípé àwọn ọ̀rọ̀ náà kìí se òtítọ́, ó ni ẹ̀tàn nínú ó sì jẹ́ iṣé àwọn oníjìbìtì. Oládòkun sọ wípé Adéṣínà kò ṣàtìlẹyìn fún ẹnikẹ́ni Irọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí Àmóọ̀, àwọn ọmọlẹ́yìn Tinubu tẹ̀síwájú láti tẹ ìròyìn yìí ránṣẹ́ káàkiri lórí Facebook.
(vi)
|