?:reviewBody
|
-
NÍ ÈDÈ KÚKÚRÚ : Ilé asòfin àgbà ti orílẹ̀dè Nàìjíríà ti ní kí ilé ìfowópamọ́ tí ó gajù ní orílẹ̀dè ọ̀hún fi ọjọ́ kún ìgbà tí wọ́n lè ná owó àtijọ́. Ṣùgbọ́n, bí ó tilẹ̀ jẹ́pé oríṣiríṣi àhésọ ni ó wà lórí àwọn òpó ìkànsíaraẹni, ilé ìfowópamọ́ ọ̀hún kòì kéde bóyá yíò fi ọjọ́ kún ìgbà tí ó dá àtipé ọjọ́ tí wọ̣́n dá fún àwọn èèyàn láti ná owó àtijọ́ náà dà ni ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kínní ọdún 2023. Ní yàjóyàjó: Wọ́n ti fi ọjọ́ kún àkokò tí a lè ná Naira àtijó dà di oṣù kẹ́fà, àtẹ̀jáde orí Facebook kan tí a gbé síta lọ́jọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù kejìlá ọdún 2022 ni ó kà báyìí. Ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹwa , Godwin Emefiele, gómínà Central Bank ti orílẹ̀dè Nàìjíríà (CBN) kéde ètò láti tún N200, N500 àti N1,000 tí wọ́́n ná lórílẹ̀dè náà tẹ̀. Ó sọwípé àtúntẹ̀ rẹ̀ jé ìgbéṣè láti kojú àwọn ìsòrò tí ó ní ṣe pẹ̀lú bí ǹkan ṣe túbò ń wọ́n si, títẹ owó tí ó jẹ́ ayédèrú síta, ààbò tí kò péye àti àwọn ìṣòro míràn. Emefiele sọpé àwọn ọmọ orílẹ̀dè Nàìjíríà ní di ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kínní ọdún 2023 láti pààrọ̀ Naira tí ó wà lọwọ wọn pẹ̀ĺú tuntun èyí tí wọn ṣè ṣe. Lẹ́yìn àtúntẹ̀ owó yìí, àjọ CBN gbé òfin tuntun síta lórí iye tí èèyàn lè gbà síta ní èkan. Wọ́n nípé owó tó pọ̀jù tí èèyàn lè gbà síta lórí kántà ni N100,000 lọ́sẹ̀ fún èèyàn kan àti N500,000 lọ́sẹ̀ fún àwọn ilé iṣẹ́. Àjọ́ CBN padà ṣe àtúnṣe sí iye tí èèyàn lè gbà jáde, wọ́n sọpé èèyàn kan lè wá gbà tó N500,000 lọ́sẹ̀, àti milionu maarun naira fún ilé isẹ́ Nígbà tí ó kù díè tí oṣù kejìlá ọdún 2022 ma wá sópin, ilé ìgbìmọ̀ asòfin àgbà ní kí CBN ó fi ọjọ kún ìgbà tí wọ́n dá fún àwọn èèyàn láti ná owó ti tẹ́lẹ̀ dà láti ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kínní ọdún 2023 títí di ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù kẹfà. Ọ̀rọ̀ pé òótọ́ ni wọ́n fi ọjọ́ kún ìgbà tí wọ́n dà fún àwọn èèyàn láti ná owó ti tẹ́lẹ̀ ni wọn tún tẹ̀ jáde lóri Facebook. Ṣùgbọ́n ṣé àjọ náà kéde báyìí? A ṣe ìwádìí. CBN kòì gbà láti ṣe ohun tí àwọn asòfin sọ Àwọn oníròyìn gbe pé àwọn ọmọ ilé asòfin àgbà ti ní kí CBN ó fi ọjọ́ kún àsìkò tí wón dá ṣùgbọ́n wọn kòì tí padà gbé ìròyìn bóyá CBN ti gbà láti fi àsìkò kun. Ní oṣù kọkànlá ọdún 2022 , CBN tweet pé Naira ti tẹ́lẹ̀ yíò ṣe ná títí di ọjọ́ kọkànlélọgbọ̀n oṣù kínní ọdún 2023 sùgbón won kòì tí gbé ìròyìn míràn jáde nípa pé wọ́n fi àsìkò kun. A kò lè fìdí òtító ohun tí wọ́n tẹ̀ lórí àwọn òpó ìkànsíaraẹni múlẹ̀.
(vi)
|