PropertyValue
?:author
?:datePublished
  • 2022-10-19 (xsd:date)
?:headline
  • Rárá, olùdíje dupò ààrẹ lábẹ́ ẹgbé òṣèlú tí ó ń se ìjọba lọ́wọ́, Bola Tinubu kò sọpé òhun kò díje mọ́ (vi)
?:inLanguage
?:itemReviewed
?:mentions
?:reviewBody
  • NÍ ÈDÈ KÚKÚRÚ : A ti ń rí oríṣiríṣi ìròyìn tí ó lè ṣini lọ́nà tí ó ń káàkiri òpó ìkànsíaraẹni ní orílẹ̀dè Nàìjíríà láti ìgbà tí Bola Tinubu ti sọpé òhun yíò díje dupò ààrẹ lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú tí ó ń ṣè ìjọba lọ́wọ́ ní oṣù kínní ọdún 2022. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀rọ̀ àhésọ míràn, àwọn ìròyìn èké pé kò díje mọ́ nítorí àìlera rẹ̀ náà jẹ́ iró gbáà. Bola Ahmed Tinubu kò díje dupò ààrẹ mọ́ nítorí àìlera rẹ̀, báyìí ni àtẹ̀ránṣẹ́ kan nínú ẹgbẹ́ orí Facebook kan ní orílẹ̀dẹ̀ Nàìjíríà tí ó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlàádọ́ta eèyàn wà ṣe bẹ̀rẹ̀. Ó sọ pẹ̀lú àrídájú wípé Bola Tinubu kò díje nínú ètò ìdìbò 2023 mọ́ lẹ́yìn tí dókítà rẹ̀ kìlọ̀ fun láti dá ìpinnu rẹ̀ láti díje dupò ààrẹ dúró nítorí ìlera rẹ̀. Ìfiránṣẹ́ òhún kà báyìí : Àwọn dókítà tí ó ń ṣètọ́jú aláìsàn tí ó ń díje dupò ààrẹ lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC Ọ̀gbẹ́ni Yekini Amoda (Tí gbogbo èyàn mọ̀ sí Bola Ahmed Tinubu) ni àwọn dókítà rẹ̀ ti gbà nímọ̀ràn láti fòpin sí ìlàkàkà rẹ̀ láti di ààrẹ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ó tọ́kasí ilé iṣẹ́ oníròyìn Reuters gẹ́gẹ́ bi orísun ìròyìn náà. Tinubu jẹ́ olùdíje dupò ààrẹ lábẹ́ ẹgḅé òṣèlú tí ó ń ṣe ìjoba lọ́wọ́lọ́wọ́ lórílẹ̀dè Nàìjíríà, All Progressives Congress (APC), ọ̀kan láàrín àwọn olùfigagbága gbòógì nínú ètò ìdìbò gbogboògbò lórílẹ̀dè náà ní ọdún 2023. Ó jẹ́ gómínà ìpínlẹ̀ Èkó tẹ́lẹ̀rí ní apá gúúsù ìwọ̀-oòrùn orílẹ̀dè Nàìjíríà. Láti ìgbà tí Tinubu ti fi ìpinnu rẹ̀ hàn láti díje dupò ààrẹ ní oṣù kínní ọdún 2022, ni awuyewuye tiwà nípa ẹni tí ó jẹ́ gan gan àti ipò ìlera rẹ̀ . Ní ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹsan, ọj̣́o kan lẹ́yìn tí ìpolongo ìbò bẹ̀rẹ̀ ní pereu lórílẹ̀dè Nàìjíríà ni àwọn olùdíje dupò ààrẹ bọwọ́ lu ìwé àdéhùn kí àláfíà ó jọba ní Abuja olúìlú orílẹ̀dè Nàìjíríà. Sùgbọn nítorí pé Tinubu kò síníbi tí wọ́n ti bọwọ́lu àdéhùn òhún túbọ̀ jẹ́ kí awuyewuye nípa ìlera rẹ̀ ó túbọ̀ gbinlẹ̀ si. A rí àwọn àtẹ̀ránṣẹ́ míràn tí ó ní ọ̀rọ wọ́n ní wọ́n pé nípa bí Tinubu ṣe sọpé òhun kò díje mọ́ lórí Facebook ní ibí , ibi ́ ati ibí . Ṣùgbọ́n ṣé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ àhésọ yìí? A ṣe ìwádìí. Gbóra, ìlera pípé, àti ṣíṣetán láti sìn’ A wo orí webusite Reuters ṣùgbọ́n a kò rí ìròyìn pé Tinubu kò díje dupò ààrẹ mọ́. Ní ọjọ́ kejì oṣù kẹwa, Bola Tinubu tẹ ọ̀rọ̀ jáde láti orí orúkọ ìdánimọ̀ rẹ̀ tí ó ní àmì àrídájú lórí Twitter , tí ó bẹnu àtẹ lu àwọn wọ́n ní wọ́n pé tí ó ń káàkiri pé kò díje mọ́. Ó koó báyìí : Ọ̀pọ̀ èyàn ti sọ pé mo ti kú, àwọn míràn nípé mi ò díje dupò ààrẹ mọ́. Àmóò... Irọ́ ni. Ó nípé òhun gbóra, òhún wà ní ìlera pípé bẹ gẹ́gẹ́ ni òhun sì SETÁN láti sin àwọn ọmọ orílẹ̀dè Nàìjíríà láti ìbẹ̀rẹ̀ wá. Ọmọ aadọrin ọdún náà tẹ fídíò ibi tí ó ti ń gun kẹ̀kẹ́ eré ìdárayá kan ránṣẹ́. Ní ọjọ́ kẹwa oṣù kẹwa, ní ìlú Abuja, Tinubu ṣe ìfilọ́lẹ̀ igun àwọn obìnrin nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC tí ó wà fún ìpolongo ìdíje duṕo ààrẹ rẹ̀. Kò sí ohun tí ó fihàn pé ìpolongo ọ̀hún falẹ̀ rárá. (vi)
?:reviewRating
rdf:type
?:url